10. Juda si tọ̀ awọn ara Kenaani ti ngbé Hebroni lọ: (orukọ Hebroni ni ìgba iṣaju si ni Kiriati-arba:) nwọn si pa Ṣeṣai, ati Ahimani, ati Talmai.
11. Lati ibẹ̀ o si gbé ogun tọ̀ awọn ara Debiri lọ. (Orukọ Debiri ni ìgba atijọ si ni Kiriati-seferi.)
12. Kalebu si wipe, Ẹniti o ba kọlù Kiriati-seferi, ti o si kó o, on li emi o fi Aksa ọmọbinrin mi fun li aya.
13. Otnieli ọmọ Kenasi, aburò Kalebu, si kó o: o si fi Aksa ọmọbinrin rẹ̀ fun u li aya.
14. O si ṣe, nigbati Aksa dé ọdọ rẹ̀, o si rọ̀ ọ lati bère oko kan lọdọ baba rẹ̀: Aksa si sọkalẹ kuro lori kẹtẹkẹtẹ rẹ̀; Kalebu si wi fun u pe, Kini iwọ nfẹ́?
15. On si wi fun u pe, Ta mi lọrẹ kan; nitoriti iwọ ti fun mi ni ilẹ Gusù, fi isun omi fun mi pẹlu. Kalebu si fi ìsun òke ati isun isalẹ fun u.