Tẹsalonika Kinni 5:5-7 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Nítorí ọmọ ìmọ́lẹ̀ ni gbogbo yín; ọmọ tí a bí ní àkókò tí ojú ti là sí òtítọ́, ẹ kì í ṣe àwọn tí a bí ní àkókò àìmọ̀kan; ẹ kì í ṣe ọmọ òkùnkùn.

6. Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí á máa sùn bí àwọn yòókù, ṣugbọn ẹ jẹ́ kí á máa ṣọ́nà, kí á sì máa ṣọ́ra.

7. Nítorí òru ni àwọn tí ń sùn ń sùn, òru sì ni àwọn tí ó ń mutí ń mutí.

Tẹsalonika Kinni 5