9. Kò nílò pé a tún ń kọ̀wé si yín nípa ọ̀rọ̀ ìfẹ́ láàrin àwọn onigbagbọ, nítorí Ọlọrun ti kọ́ ẹ̀yin fúnra yín láti fẹ́ràn ọmọnikeji yín.
10. Bẹ́ẹ̀ gan-an ni ẹ sì ń ṣe sí gbogbo àwọn onigbagbọ ní gbogbo Masedonia. Ẹ̀yin ará, mò ń rọ̀ yín, ẹ túbọ̀ máa ṣe bẹ́ẹ̀ ati jù bẹ́ẹ̀ lọ.
11. Ẹ gbìyànjú láti fi ọkàn yín balẹ̀. Ẹ má máa yọjú sí nǹkan oní-ǹkan. Ẹ tẹpá mọ́ṣẹ́, gẹ́gẹ́ bí a ti sọ fun yín.
12. Ẹ máa rìn bí ó ti yẹ láàrin àwọn alaigbagbọ, kí ó má sí pé ẹ nílò ati gba ohunkohun lọ́wọ́ wọn.
13. Ẹ̀yin ará, àwa kò fẹ́ kí ẹ má ní òye nípa àwọn tí wọ́n ti sùn, kí ẹ má baà banújẹ́ bí àwọn tí kò nírètí.
14. Nítorí bí a bá gbàgbọ́ pé Jesu kú, ó sì jinde, bẹ́ẹ̀ gan-an ni Ọlọrun yóo mú àwọn tí wọ́n ti kú ninu Jesu wà pẹlu rẹ̀.