Tẹsalonika Kinni 2:17-20 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Ẹ̀yin ará, nígbà tí a kúrò lọ́dọ̀ yín fún ìgbà díẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a pínyà nípa ti ara, sibẹ ọkàn wa kò kúrò lọ́dọ̀ yín, ọkàn yín tún ń fà wá gan-an ni.

18. A fẹ́ wá sọ́dọ̀ yín. Kì í ṣe ọ̀rọ̀ ẹ̀ẹ̀kan tabi ẹẹmeji ni èmi Paulu ti fẹ́ wá, ṣugbọn Satani dí wa lọ́wọ́.

19. Nítorí tí kò bá ṣe ẹ̀yin, ta tún ni ìrètí wa, ayọ̀ wa, ati adé tí a óo máa fi ṣògo níwájú Oluwa wa Jesu nígbà tí ó bá farahàn?

20. Ẹ̀yin ni ògo wa ati ayọ̀ wa.

Tẹsalonika Kinni 2