Samuẹli Kinni 9:1-2 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ọkunrin ọlọ́rọ̀ kan wà, orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kiṣi, ọmọ Abieli, ọmọ Serori, ọmọ Bekorati, ọmọ Afaya láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini.

2. Ó ní ọmọkunrin kan tí ń jẹ́ Saulu. Saulu yìí jẹ́ arẹwà ọkunrin. Láti èjìká rẹ̀ sókè ni ó fi ga ju ẹnikẹ́ni ninu àwọn ọmọ Israẹli lọ, ó sì lẹ́wà ju ẹnikẹ́ni ninu wọn lọ.

Samuẹli Kinni 9