3. Wọ́n dá wọn lóhùn pé, “Bí ẹ óo bá dá àpótí Ọlọrun Israẹli pada, ẹ gbọdọ̀ dá a pada pẹlu ẹbọ ìmúkúrò ẹ̀bi, àpótí ẹ̀rí náà kò gbọdọ̀ pada lọ lásán, láìsí nǹkan ètùtù. Bẹ́ẹ̀ ni ara yín yóo ṣe yá, ẹ óo sì mọ ìdí tí Ọlọrun fi ń jẹ yín níyà.”
4. Àwọn eniyan náà bi wọ́n pé, “Kí ni kí á fi ranṣẹ gẹ́gẹ́ bí nǹkan ètùtù?”Àwọn babalóòṣà dá wọn lóhùn pé, “Ẹ fi wúrà yá ère kókó ọlọ́yún marun-un, ati ti èkúté marun-un, kí ẹ fi ranṣẹ. Kókó ọlọ́yún wúrà marun-un ati èkúté marun-un dúró fún àwọn ọba Filistini maraarun. Nítorí àjàkálẹ̀ àrùn kan náà ni ó kọlu gbogbo yín ati àwọn ọba yín maraarun.
5. Ẹ gbọdọ̀ fi wúrà yá ère kókó ọlọ́yún yín ati ti èkúté tí ń ba ilẹ̀ yín jẹ́, kí ẹ sì fi ògo fún Ọlọrun Israẹli bóyá ó lè dáwọ́ ìjìyà rẹ̀ dúró lórí ẹ̀yin ati oriṣa yín, ati ilẹ̀ yín.
6. Kí ló dé tí ẹ fi fẹ́ ṣe oríkunkun, bí ọba ilẹ̀ Ijipti ati àwọn ará Ijipti. Ẹ ranti bí Ọlọrun ti fi wọ́n ṣe ẹlẹ́yà títí tí wọ́n fi jẹ́ kí àwọn ọmọ Israẹli lọ. Wọ́n kúkú lọ!
7. Nítorí náà ẹ kan kẹ̀kẹ́ ẹrù tuntun kan, kí ẹ sì tọ́jú abo mààlúù meji tí ń fún ọmọ lọ́mú tí ẹnikẹ́ni kò sì so àjàgà mọ́ lọ́rùn rí, ẹ so kẹ̀kẹ́ ẹrù náà mọ́ wọn lọ́rùn, kí ẹ sì lé àwọn ọmọ wọn pada sílé.