Samuẹli Kinni 25:42-44 BIBELI MIMỌ (BM)

42. Ó yára gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀, òun pẹlu àwọn iranṣẹbinrin rẹ̀ marun-un, wọ́n sì tẹ̀lé àwọn iranṣẹ Dafidi lọ, Abigaili sì di aya Dafidi.

43. Dafidi ti fẹ́ Ahinoamu ará Jesireeli, ó sì tún fẹ́ Abigaili pẹlu.

44. Ṣugbọn Saulu ti mú Mikali, ọmọ rẹ̀ tí ó jẹ́ iyawo Dafidi, ó ti fún Paliti ọmọ Laiṣi tí ó wá láti Galimu pé kí ó fi ṣe aya.

Samuẹli Kinni 25