Samuẹli Kinni 18:29-30 BIBELI MIMỌ (BM)

29. Nítorí náà, ó bẹ̀rù Dafidi sí i, ó sì ń bá Dafidi ṣe ọ̀tá títí gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀.

30. Ninu gbogbo ogun tí wọ́n bá àwọn ara Filistia jà, Dafidi ní ìṣẹ́gun ju gbogbo àwọn olórí ogun Saulu yòókù lọ. Ó sì jẹ́ olókìkí láàrin wọn.

Samuẹli Kinni 18