Samuẹli Keji 5:11-17 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Hiramu ọba Tire rán àwọn oníṣẹ́ sí Dafidi. Ó fi igi Kedari ranṣẹ sí i, pẹlu àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà, ati àwọn tí wọn ń fi òkúta kọ́ ilé, pé kí wọ́n lọ kọ́ ààfin Dafidi.

12. Dafidi wá mọ̀ pé, OLUWA ti fi ìdí òun múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọba Israẹli, ó sì ti gbé ìjọba òun ga, nítorí Israẹli, àwọn eniyan rẹ̀.

13. Nígbà tí Dafidi kúrò ní Heburoni lọ sí Jerusalẹmu, ó fẹ́ àwọn obinrin mìíràn kún àwọn aya rẹ̀. Ó sì ní ọpọlọpọ ọmọ sí i, lọkunrin ati lobinrin.

14. Orúkọ àwọn tí wọ́n bí fún un ní Jerusalẹmu nìwọ̀nyí: Ṣamua ati Ṣobabu, Natani, ati Solomoni;

15. Ibihari ati Eliṣua, Nefegi ati Jafia;

16. Eliṣama, Eliada, ati Elifeleti.

17. Nígbà tí àwọn ará Filistia gbọ́ pé wọ́n ti fi Dafidi jọba Israẹli, gbogbo àwọn ọmọ ogun wọn jáde lọ láti mú un, ṣugbọn Dafidi gbọ́ pé wọ́n ń bọ̀ wá mú òun, ó bá lọ sí ibi ààbò.

Samuẹli Keji 5