15. Ọkàn ilé fa Dafidi pupọ tóbẹ́ẹ̀ tí ó fi wí pé, “Báwo ni ìbá ti dùn tó, kí ẹnìkan bu omi wá fún mi mu, láti inú kànga tí ó wà ní ẹnubodè Bẹtilẹhẹmu.”
16. Àwọn akọni ọmọ ogun mẹta yìí bá fi tipátipá la àgọ́ àwọn ará Filistia kọjá, wọ́n pọn omi láti inú kànga náà, wọ́n sì gbé e wá fún Dafidi. Ṣugbọn Dafidi kọ̀, kò mu ún. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó dà á sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ohun mímú fún OLUWA.
17. Ó sì wí pé, “OLUWA, kò yẹ kí n mu omi yìí, nítorí pé, yóo dàbí ẹni pé ẹ̀jẹ̀ àwọn ọkunrin mẹta yìí, tí wọ́n fi orí la ikú lọ ni mò ń mu.” Nítorí náà, ó kọ̀, kò mu ún.Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí jẹ́ ara àwọn nǹkan ìgboyà tí àwọn akọni ọmọ ogun mẹta náà ṣe.
18. Arakunrin Joabu, tí ń jẹ́ Abiṣai, ọmọ Seruaya ni aṣiwaju fún “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni Olókìkí.” Ó fi idà rẹ̀ pa ọọdunrun eniyan, nípa bẹ́ẹ̀, ó di olókìkí láàrin wọn.
19. Òun ni ó jẹ́ olókìkí jùlọ ninu “Àwọn Ọgbọ̀n Akọni,” ó sì di aṣiwaju wọn, ṣugbọn kò lókìkí tó “Àwọn Akọni Mẹta” àkọ́kọ́.