30. Nígbà tí Joabu pada lẹ́yìn Abineri, tí ó sì kó gbogbo àwọn eniyan rẹ̀ jọ, ó rí i pé, lẹ́yìn Asaheli, àwọn mejidinlogun ni wọn kò rí mọ́.
31. Ṣugbọn àwọn eniyan Dafidi ti pa ọtalelọọdunrun (360) ninu àwọn eniyan Abineri.
32. Joabu ati àwọn eniyan rẹ̀ bá gbé òkú Asaheli, wọ́n sì lọ sin ín sí ibojì ìdílé wọn ní Bẹtilẹhẹmu. Gbogbo òru ọjọ́ náà ni wọ́n fi rìn; ní òwúrọ̀ kutukutu ọjọ́ keji, ni wọ́n pada dé Heburoni.