Samuẹli Keji 14:12-16 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Obinrin yìí bá tún dáhùn pé, “Kabiyesi, jọ̀wọ́, jẹ́ kí n sọ gbolohun kan yìí sí i.”Ọba dáhùn pé, “Ó dára, mò ń gbọ́.”

13. Obinrin náà wí pé, “Kí ló dé tí o fi ṣe ohun tí ó burú yìí sí àwọn eniyan Ọlọrun? Ọ̀rọ̀ tí o sọ tán nisinsinyii, ara rẹ gan-an ni o fi dá lẹ́bi, nítorí pé, o kò jẹ́ kí ọmọ rẹ pada wá sílé láti ibi tí ó sá lọ?

14. Dájúdájú, gbogbo wa ni a óo kú. A dàbí omi tí ó dà sílẹ̀, tí ẹnikẹ́ni kò sì lè kójọ mọ́. Ẹni tí ó bá ti kú, Ọlọrun pàápàá kì í tún gbé e dìde mọ́, ṣugbọn kabiyesi lè wá ọ̀nà, láti fi mú ẹni tí ó bá sá jáde kúrò ní ìlú pada wálé.

15. Kabiyesi, ìdí tí mo fi kó ọ̀rọ̀ mi tọ̀ ọ́ wá ni pé, àwọn eniyan ń dẹ́rùbà mí, èyí ni ó mú kí n rò ninu ara mi pé, n óo wá bá ọ sọ̀rọ̀, mo sì ní ìrètí pé, kabiyesi yóo ṣe ohun tí mo wá bẹ̀bẹ̀ pé kí ó bá mi ṣe.

16. Mo mọ̀ pé ọba yóo fetí sílẹ̀ láti gbọ́ tèmi, yóo sì gbà mí kalẹ̀ lọ́wọ́ ẹni tí ó fẹ́ pa èmi ati ọmọ mi, tí ó sì fẹ́ pa wá run kúrò lórí ilẹ̀ tí Ọlọrun fún àwọn eniyan rẹ̀.

Samuẹli Keji 14