Romu 14:2-9 BIBELI MIMỌ (BM)

2. Ẹnìkan ní igbagbọ pé kò sí ohun tí òun kò lè jẹ, ṣugbọn ẹni tí igbagbọ rẹ̀ kò tíì fẹsẹ̀ múlẹ̀ rọra ń jẹ ẹ̀fọ́ ní tirẹ̀.

3. Kí ẹni tí ń jẹran má fi ojú tẹmbẹlu ẹni tí kì í jẹ. Kí ẹni tí kì í jẹ má sì ṣe dá ẹni tí ó ń jẹ lẹ́bi, nítorí Ọlọrun ti gbà á.

4. Ta ni ìwọ tí ò ń dá ọmọ-ọ̀dọ̀ ẹlòmíràn lẹ́jọ́? Kì báà dúró, kì báà sì ṣubú, ọ̀gá rẹ̀ nìkan ni ìdájọ́ tọ́ sí. Yóo tilẹ̀ dúró ni, nítorí Oluwa lè gbé e ró.

5. Ẹnìkan ka ọjọ́ kan sí ọjọ́ pataki ju ọjọ́ mìíràn lọ, ẹlòmíràn ka gbogbo ọjọ́ sí bákan náà. Ẹ jẹ́ kí olukuluku pinnu lọ́kàn ara rẹ̀ nípa irú ọ̀ràn báwọ̀nyí.

6. Ẹni tí ó gbé ọjọ́ kan ga ju ọjọ́ mìíràn lọ, ti Oluwa ni ó ń rò. Ẹni tí ó ń jẹ oríṣìíríṣìí oúnjẹ, ó ń jẹ ẹ́ nítorí Oluwa. Ọpẹ́ ni ó ń fi fún Ọlọrun. Ẹni tí kò jẹ, kò jẹ ẹ́ nítorí Oluwa, ọpẹ́ ni òun náà ń fi fún Ọlọrun.

7. Kò sí ẹni tí ó lè wà láàyè fún ara rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni, kò sí ẹni tí ó lè sọ pé, òun nìkan ni ikú òun kàn.

8. Bí a bá wà láàyè, Oluwa ni a wà láàyè fún. Bí a bá sì kú, Oluwa ni a kú fún. Nítorí náà, ààyè wa ni o, òkú wa ni o, ti Oluwa ni wá.

9. Ìdí tí Kristi fi kú nìyí, tí ó sì tún jí, kí ó lè jẹ́ Oluwa àwọn òkú ati ti àwọn alààyè.

Romu 14