Romu 1:22-27 BIBELI MIMỌ (BM)

22. Wọ́n ń ṣe bí ẹni pé wọ́n gbọ́n, bẹ́ẹ̀ sì ni wọ́n ya òmùgọ̀.

23. Wọ́n yí ògo Ọlọrun tí kò lè bàjẹ́ pada sí àwòrán ẹ̀dá tí yóo bàjẹ́; bíi àwòrán eniyan, ẹyẹ, ẹranko ati ejò.

24. Nítorí náà Ọlọrun fi wọ́n sílẹ̀ láti máa ṣe ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ọkàn wọn.

25. Wọ́n yí òtítọ́ Ọlọrun pada sí irọ́. Wọ́n ń bọ nǹkan tí Ọlọrun dá, wọ́n ń tẹríba fún wọn, dípò èyí tí wọn ìbá fi máa sin ẹni tí ó dá wọn, ẹni tí ìyìn yẹ fún títí lae. Amin.

26. Nítorí náà, Ọlọrun fi wọ́n sílẹ̀ fún ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ tí ó ti eniyan lójú. Àwọn obinrin wọn ń bá ara wọn ṣe ohun tí kò bójú mu.

27. Bẹ́ẹ̀ náà ni àwọn ọkunrin wọn. Dípò tí ọkunrin ìbá máa fi bá obinrin lòpọ̀, ọkunrin ati ọkunrin ni wọ́n ń dìde sí ara wọn ninu ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn. Ọkunrin ń bá ọkunrin ṣe ohun ìtìjú, wọ́n wá ń jèrè ìṣekúṣe wọn.

Romu 1