Orin Solomoni 5:3-10 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Mo ti bọ́ra sílẹ̀,báwo ni mo ṣe lè tún múra?Mo ti fọ ẹsẹ̀ mi,báwo ni mo ṣe lè tún dọ̀tí rẹ̀?

4. Olùfẹ́ mi gbọ́wọ́ lé ìlẹ̀kùn,ọkàn mi sì kún fún ayọ̀.

5. Mo dìde, mo ṣílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,gbogbo ọwọ́ mi kún fún òjíá,òróró òjíá sì ń kán ní ìka misára kọ́kọ́rọ́ ìlẹ̀kùn.

6. Mo ṣílẹ̀kùn fún olùfẹ́ mi,ṣugbọn ó ti yipada, ó ti lọ.Mo fẹ́rẹ̀ dákú, nígbà tí ó sọ̀rọ̀,mo wá a, ṣugbọn n kò rí i,mo pè é, ṣugbọn kò dáhùn.

7. Àwọn aṣọ́de rí mibí wọ́n ti ń rìn káàkiri ìlú;wọ́n lù mí, wọ́n ṣe mí léṣe,wọ́n sì gba ìborùn mi.

8. Mo rọ̀ yín, ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu,bí ẹ bá rí olùfẹ́ mi,ẹ bá mi sọ fún un pé:Àìsàn ìfẹ́ ń ṣe mí.

9. Kí ni olùfẹ́ tìrẹ fi dára ju ti àwọn yòókù lọ?Ìwọ arẹwà jùlọ láàrin àwọn obinrin?Kí ni olùfẹ́ rẹ fi dára ju ti àwọn yòókù lọ?Tí o fi ń kìlọ̀ fún wa bẹ́ẹ̀?

10. Olùfẹ́ mi lẹ́wà pupọ, ó sì pupa,ó yàtọ̀ láàrin ẹgbaarun (10,000) ọkunrin.

Orin Solomoni 5