Orin Solomoni 5:1-2 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Mo wọ inú ọgbà mi,arabinrin mi, iyawo mi.Mo kó òjíá ati àwọn turari olóòórùn dídùn mi jọ,mo jẹ afárá oyin mi, pẹlu oyin inú rẹ̀,mo mu waini mi ati wàrà mi.Ẹ̀yin ọ̀rẹ́ mi, ẹ jẹ, kí ẹ sì mu,ẹ mu àmutẹ́rùn, ẹ̀yin olùfẹ́.

2. Mo sùn ṣugbọn ọkàn mi kò sùn.Ẹ gbọ́! Olùfẹ́ mi ń kan ìlẹ̀kùn.Ṣílẹ̀kùn fún mi,arabinrin mi, olùfẹ́ mi,àdàbà mi, olùfẹ́ mi tí ó péye,nítorí pé, ìrì ti mú kí orí mi tutù,gbogbo irun mi ti rẹ, fún ìrì alẹ́.

Orin Solomoni 5