4. Fà mí mọ́ra, jẹ́ kí á ṣe kíá,ọba ti mú mi wọ yàrá rẹ̀.Inú wa yóo máa dùn, a óo sì máa yọ̀ nítorí rẹa óo gbé ìfẹ́ rẹ ga ju ọtí waini lọ;abájọ tí gbogbo àwọn obinrin ṣe fẹ́ràn rẹ!
5. Ẹ̀yin ọmọbinrin Jerusalẹmu,mo dúdú lóòótọ́, ṣugbọn mo lẹ́wà,mo dàbí àgọ́ Kedari,mo rí bí aṣọ títa tí ó wà ní ààfin Solomoni.
6. Má wò mí tìka-tẹ̀gbin, nítorí pé mo dúdú,oòrùn tó pa mí ló ṣe àwọ̀ mi bẹ́ẹ̀.Àwọn ọmọ ìyá mi lọkunrin bínú sí mi,wọ́n fi mí ṣe olùtọ́jú ọgbà àjàrà,ṣugbọn n kò tọ́jú ọgbà àjàrà tèmi alára.