Orin Dafidi 99:7-9 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ó bá wọn sọ̀rọ̀ ninu ọ̀wọ̀n ìkùukùu;wọ́n pa òfin rẹ̀ mọ́;wọ́n sì tẹ̀lé ìlànà tí ó fún wọn.

8. OLUWA Ọlọrun wa, o dá wọn lóhùn;Ọlọrun tíí dáríjì ni ni o jẹ́ fún wọn;ṣugbọn ó gbẹ̀san ìwàkiwà wọn.

9. Ẹ yin OLUWA, Ọlọrun wa,kí ẹ sì jọ́sìn níbi òkè mímọ́ rẹ̀;nítorí pé mímọ́ ni OLUWA Ọlọrun wa.

Orin Dafidi 99