Orin Dafidi 94:14-17 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Nítorí OLUWA kò ní kọ àwọn eniyan rẹ̀ sílẹ̀;kò ní ṣá àwọn eniyan ìní rẹ̀ tì;

15. nítorí pé ìdájọ́ òtítọ́ yóo pada jẹ́ ìpín àwọn olódodo,àwọn olóòótọ́ yóo sì máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.

16. Ta ni yóo bá mi dìde sí àwọn eniyan burúkú?Ta ni yóo bá mi dìde sí àwọn aṣebi?

17. Bí kì í bá ṣe pé OLUWA ràn mí lọ́wọ́,ǹ bá ti dákẹ́ jẹ́ẹ́ ní isà òkú.

Orin Dafidi 94