Orin Dafidi 92:12-14 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Àwọn olódodo yóo gbilẹ̀ bí igi ọ̀pẹ,wọn óo dàgbà bí igi kedari ti Lẹbanoni.

13. Wọ́n dàbí igi tí a gbìn sí ilé OLUWA,tí ó sì ń dàgbà ninu àgbàlá Ọlọrun wa.

14. Wọn á máa so èso títí di ọjọ́ ogbó wọn,wọn á máa lómi lára, ewé wọn á sì máa tutù nígbà gbogbo;

Orin Dafidi 92