8. Yóo fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé,yóo sì fi ẹ̀tọ́ ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè.
9. OLUWA ni ààbò fún àwọn tí a ni lára,òun ni ibi ìsádi ní ìgbà ìpọ́njú.
10. Àwọn tí ó mọ̀ ọ́ yóo gbẹ́kẹ̀lé ọ;nítorí ìwọ, OLUWA, kìí kọ àwọn tí ń wá ọ sílẹ̀.
11. Ẹ kọrin ìyìn sí OLUWA, tí ó gúnwà ní Sioni!Ẹ kéde iṣẹ́ rẹ̀ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè!
12. Nítorí olùgbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ ranti,kò sì gbàgbé igbe ẹkún àwọn tí a pọ́n lójú.
13. OLUWA, ṣàánú fún mi!Wò ó bí àwọn ọ̀tá mi ṣe ń pọ́n mi lójú.Gbà mí kúrò létí bèbè ikú,
14. kí n lè kọrin ìyìn rẹ,kí n sì lè yọ ayọ̀ ìgbàlà rẹ lẹ́nu ibodè Sioni.
15. Àwọn orílẹ̀-èdè ti jìn sinu kòtò tí wọ́n gbẹ́,wọ́n sì ti kó sinu àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀.
16. OLUWA ti fi ara rẹ̀ hàn, ó ti ṣe ìdájọ́,àwọn eniyan burúkú sì ti kó sinu tàkúté ara wọn.
17. Àwọn eniyan burúkú,àní, gbogbo orílẹ̀-èdè tí ó gbàgbé Ọlọrun, ni yóo lọ sinu isà òkú.