Orin Dafidi 71:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA, ìwọ ni mo sá di;má jẹ́ kí ojú ó tì mí laelae!

2. Gbà mí, kí o sì yọ mí nítorí òdodo rẹ;tẹ́tí sí mi kí o sì gbà mí là!

3. Máa ṣe àpáta ààbò fún mi,jẹ́ odi alágbára fún mi kí o sì gbà mí,nítorí ìwọ ni ààbò ati odi mi.

4. Ọlọrun mi, gbà mí lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú,àwọn alaiṣootọ ati ìkà.

Orin Dafidi 71