Orin Dafidi 7:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA, Ọlọrun mi, ìwọ ni mo sá di;gbà mí là, kí o sì yọ mí lọ́wọ́ àwọn tí ń lépa mi.

2. Kí wọn má baà fà mí ya bíi kinniun,kí wọn máa wọ́ mi lọ láìsí ẹni tí ó lè gbà mí sílẹ̀.

3. OLUWA, Ọlọrun mi, bí mo bá ṣe nǹkan yìí,bí iṣẹ́ ibi bá ń bẹ lọ́wọ́ mi,

4. bí mo bá fi ibi san án fún olóore,tabi tí mo bá kó ọ̀tá mi lẹ́rú láìnídìí,

Orin Dafidi 7