Orin Dafidi 65:11-13 BIBELI MIMỌ (BM)

11. O mú kí ìkórè oko pọ̀ yanturu ní òpin ọdún;gbogbo ipa ọ̀nà rẹ sì kún fún ọpọlọpọ ìkórè oko.

12. Gbogbo pápá oko kún fún ẹran ọ̀sìn,àwọn ẹ̀gbẹ́ òkè sì kún fún ohun ayọ̀,

13. ẹran ọ̀sìn bo pápá oko bí aṣọ,ọkà bo gbogbo àfonífojì, ó sì so jìngbìnnì,wọ́n ń hó, wọ́n sì ń kọrin ayọ̀.

Orin Dafidi 65