Orin Dafidi 51:13-15 BIBELI MIMỌ (BM)

13. Nígbà náà ni n óo máa kọ́ àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ ní ọ̀nà rẹ,àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ yóo sì máa yipada sí ọ.

14. Gbà mí lọ́wọ́ ẹ̀bi ìpànìyàn, Ọlọrun,ìwọ Ọlọrun, Olùgbàlà mi,n óo sì máa fi orin kéde iṣẹ́ rere rẹ.

15. OLUWA, là mí ní ohùn,n óo sì máa ròyìn iṣẹ́ ńlá rẹ.

Orin Dafidi 51