Orin Dafidi 50:3-9 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Ọlọrun wa ń bọ̀, kò dákẹ́:iná ajónirun ń jó níwájú rẹ̀;ìjì líle sì ń jà yí i ká.

4. Ó ké sí ọ̀run lókè;ó pe ayé pẹlu láti gbọ́ ìdájọ́ tí yóo ṣe fún àwọn eniyan rẹ̀.

5. Ó ní, “Ẹ kó àwọn olùfọkànsìn mi jọ sọ́dọ̀ mi,àwọn tí wọ́n ti fi ẹbọ bá mi dá majẹmu!”

6. Ojú ọ̀run ń kéde òdodo rẹ̀ péỌlọrun ni onídàájọ́.

7. “Ẹ gbọ́, ẹ̀yin eniyan mi, n óo sọ̀rọ̀,Israẹli, n óo takò yín.Èmi ni Ọlọrun, Ọlọrun yín.

8. N kò ba yín wí nítorí ẹbọ rírú;nígbà gbogbo ni ẹ̀ ń rú ẹbọ sísun sí mi.

9. N kò ní gba akọ mààlúù lọ́wọ́ yín,tabi òbúkọ láti agbo ẹran yín.

Orin Dafidi 50