Orin Dafidi 39:8-11 BIBELI MIMỌ (BM)

8. Gbà mí ninu gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ ìrékọjá mi;má sọ mí di ẹni ẹ̀gàn lójú àwọn òmùgọ̀.

9. Mo dákẹ́, n kò ya ẹnu mi;nítorí pé ìwọ ni o ṣe é.

10. Dáwọ́ ẹgba rẹ dúró lára mi,mo ti fẹ́rẹ̀ kú nítorí ìyà tí o fi ń jẹ mí.

11. Nígbà tí o bá jẹ eniyan níyàpẹlu ìbáwí nítorí ẹ̀ṣẹ̀,ìwọ á ba ohun tí ó ṣọ̀wọ́n fún un jẹ́ bíi kòkòrò aṣọ.Dájúdájú, afẹ́fẹ́ lásán ni eniyan.

Orin Dafidi 39