Orin Dafidi 38:6-11 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Ìbànújẹ́ dorí mi kodò patapata,mo sì ń ṣọ̀fọ̀ kiri tọ̀sán-tòru.

7. Gbogbo ẹ̀gbẹ́ mi ń gbóná fòò,kò sí ibìkan tí ó gbádùn lára mi.

8. Àárẹ̀ mú mi patapata, gbogbo ara sì wó mi;mò ń kérora nítorí ẹ̀dùn ọkàn mi.

9. OLUWA, gbogbo ìfẹ́ ọkàn mi ni o mọ̀,ìmí ẹ̀dùn mi kò sì pamọ́ fún ọ.

10. Àyà mi ń lù pì pì pì, ó rẹ̀ mí láti inú wá;ojú mi sì ti di bàìbàì.

11. Àwọn ọ̀rẹ́ ati àwọn ẹlẹgbẹ́ mi takété sí mi nítorí àrùn mi,àwọn ẹbí mi sì dúró lókèèrè réré.

Orin Dafidi 38