Orin Dafidi 37:16-19 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Nǹkan díẹ̀ tí olódodo nídára ju ọ̀pọ̀ ọrọ̀ àwọn eniyan burúkú.

17. Nítorí OLUWA yóo ṣẹ́ apá eniyan burúkú,ṣugbọn yóo gbé olódodo ró.

18. OLUWA a máa tọ́jú àwọn aláìlẹ́bi;ilẹ̀ ìní wọn yóo jẹ́ tiwọn títí lae.

19. Ojú kò ní tì wọ́n nígbà tí àjálù bá dé;bí ìyàn tilẹ̀ mú, wọn óo jẹ, wọn óo yó.

Orin Dafidi 37