Orin Dafidi 35:6-12 BIBELI MIMỌ (BM)

6. Jẹ́ kí ojú ọ̀nà wọn ṣóòkùn, kí ó sì máa yọ̀,kí angẹli OLUWA máa lépa wọn!

7. Nítorí wọ́n dẹ àwọ̀n sílẹ̀ fún mi láìnídìí,wọ́n sì gbẹ́ kòtò sílẹ̀ dè mí láìnídìí.

8. Jẹ́ kí ìparun dé bá wọn lójijì,jẹ́ kí àwọ̀n tí wọ́n dẹ sílẹ̀ dè mí mú wọn;jẹ́ kí wọ́n kó sinu rẹ̀, kí wọ́n sì parun!

9. Nígbà náà ni n óo máa yọ̀ ninu OLUWA,n óo sì yọ ayọ̀ ńlá nítorí ìgbàlà rẹ̀.

10. N óo fi gbogbo ara wí pé,“OLUWA, ta ni ó dàbí rẹ?Ìwọ ni ò ń gba aláìlágbáralọ́wọ́ ẹni tí ó lágbáratí o sì ń gba aláìlágbára ati aláìnílọ́wọ́ ẹni tí ó fẹ́ fi wọ́n ṣe ìjẹ.”

11. Àwọn tí ń fi ìlara jẹ́rìí èké dìde sí mi;wọ́n ń bi mí léèrè ohun tí n kò mọ̀dí.

12. Wọ́n fi ibi san oore fún mi,ọkàn mi sì rẹ̀wẹ̀sì.

Orin Dafidi 35