Orin Dafidi 35:1-5 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA, gbógun ti àwọn tí ń gbógun tì mí;gbé ìjà ko àwọn tí ń bá mi jà!

2. Gbá asà ati apata mú,dìde, kí o sì ràn mí lọ́wọ́!

3. Fa ọ̀kọ̀ yọ kí o sì dojú kọ àwọn tí ń lépa mi!Ṣe ìlérí fún mi pé, ìwọ ni olùgbàlà mi.

4. Jẹ́ kí ojú ó ti àwọn tí ń lépa ẹ̀mí mi,kí wọn ó tẹ́!Jẹ́ kí àwọn tí ń gbìmọ̀ ibi sí mi dààmú,kí wọ́n sì sá pada sẹ́yìn!

5. Kí wọ́n dàbí fùlùfúlù ninu afẹ́fẹ́,kí angẹli OLUWA máa lé wọn lọ!

Orin Dafidi 35