Orin Dafidi 25:20-22 BIBELI MIMỌ (BM)

20. Pa mí mọ́, kí o sì gbà mí;má jẹ́ kí ojú kí ó tì mí,nítorí ìwọ ni mo sá di.

21. Nítorí pípé mi ati òdodo mi, pa mí mọ́,nítorí pé ìwọ ni mo gbẹ́kẹ̀lé.

22. Ọlọrun, ra Israẹli pada,kúrò ninu gbogbo ìyọnu rẹ̀.

Orin Dafidi 25