Orin Dafidi 19:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ojú ọ̀run ń sọ̀rọ̀ ògo Ọlọrun,òfuurufú sì ń kéde iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀.

2. Ọjọ́ dé ọjọ́ ń sọ ọ́ ní àsọgbàòru dé òru sì ń fi ìmọ̀ rẹ̀ hàn.

3. Wọn kò fọ èdè kankan, wọn kò sì sọ ọ̀rọ̀;bẹ́ẹ̀ ni a kò gbọ́ ohùn wọn;

Orin Dafidi 19