Orin Dafidi 148:4-9 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Ẹ yìn ín, ọ̀run tí ó ga jùlọ;yìn ín, omi tí ó wà lójú ọ̀run.

5. Ẹ jẹ́ kí wọ́n máa yin orúkọ OLUWA,nítorí nípa àṣẹ rẹ̀ ni a fi dá wọn.

6. Ó fi ìdí wọn múlẹ̀ títí laelae;ó sì pààlà fún wọn tí wọn kò gbọdọ̀ ré kọjá.

7. Ẹ yin OLUWA, ẹ̀yin ẹ̀dá ayé,ẹ̀yin erinmi ńláńlá inú òkun ati gbogbo ibú omi;

8. iná ati yìnyín, ati ìrì dídì,ati ẹ̀fúùfù líle tí ń mú àṣẹ rẹ̀ ṣẹ.

9. Ẹ yìn ín, ẹ̀yin òkè ńláńlá ati òkè kéékèèké,ẹ̀yin igi eléso ati igi kedari;

Orin Dafidi 148