Orin Dafidi 140:4-7 BIBELI MIMỌ (BM)

4. OLUWA, ṣọ́ mi lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú;dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn oníwà ipá,tí ó ń gbìmọ̀ láti ré mi lẹ́pa.

5. Àwọn agbéraga ti dẹ tàkúté sílẹ̀ dè mí,wọ́n dẹ àwọ̀n sílẹ̀ fún mi;wọ́n sì dẹ okùn sílẹ̀ fún mi lẹ́bàá ọ̀nà.

6. Mo wí fún OLUWA pé, “Ìwọ ni Ọlọrun mi.”OLUWA, tẹ́tí sí ohùn ẹ̀bẹ̀ mi.

7. OLUWA, OLUWA mi, alágbára tíí gbani là,ìwọ ni o dáàbò bò mí ní ọjọ́ ogun.

Orin Dafidi 140