Orin Dafidi 120:1-4 BIBELI MIMỌ (BM)

1. OLUWA ni mo ké pè, nígbà tí mo wà ninu ìpọ́njú,ó sì dá mi lóhùn.

2. OLUWA, gbà mí lọ́wọ́ àwọn èké,ati lọ́wọ́ àwọn ẹlẹ́tàn.

3. Kí ni a óo fi san án fun yín?Kí ni a óo sì ṣe si yín, ẹ̀yin ẹlẹ́tàn?

4. Ọfà mímú ni a óo ta yín,a óo sì dáná sun yín.

Orin Dafidi 120