Orin Dafidi 119:32-36 BIBELI MIMỌ (BM)

32. N óo yára láti pa òfin rẹ mọ́,nígbà tí o bá mú òye mi jinlẹ̀ sí i.

33. OLUWA, kọ́ mi ní ìlànà rẹ,n óo sì pa wọ́n mọ́ dé òpin.

34. Là mí lóye, kí n lè máa pa òfin rẹ mọ́,kí n sì máa fi tọkàntọkàn pa wọ́n mọ́.

35. Tọ́ mi sí ọ̀nà nípa òfin rẹ,nítorí pé mo láyọ̀ ninu rẹ̀.

36. Mú kí ọkàn mi fà sí òfin rẹ,kí ó má fà sí ọrọ̀ ayé.

Orin Dafidi 119