Orin Dafidi 106:28-31 BIBELI MIMỌ (BM)

28. Wọ́n da ara wọn pọ̀ mọ́ Baali ti Peori,wọ́n sì ń jẹ ẹbọ tí wọ́n rú sí òkú.

29. Wọ́n fi ìwà burúkú wọn mú OLUWA bínú,àjàkálẹ̀ àrùn sì bẹ́ sílẹ̀ láàrin wọn.

30. Nígbà náà ni Finehasi dìde, ó bẹ̀bẹ̀ fún wọn,àjàkálẹ̀ àrùn sì dáwọ́ dúró.

31. A sì kà á kún òdodo fún un,láti ìrandíran títí lae.

Orin Dafidi 106