Orin Dafidi 106:17-21 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Ilẹ̀ yanu, ó gbé Datani mì,ó sì bo Abiramu ati àwọn tí ó tẹ̀lé e mọ́lẹ̀.

18. Iná sọ láàrin wọn,ó sì jó àwọn eniyan burúkú náà run.

19. Wọ́n yá ère ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù ní Horebu,wọ́n sì bọ ère tí wọ́n dà.

20. Wọ́n gbé ògo Ọlọrunfún ère mààlúù tí ń jẹ koríko.

21. Wọ́n gbàgbé Ọlọrun, Olùgbàlà wọn,tí ó ṣe iṣẹ́ ribiribi ní Ijipti,

Orin Dafidi 106