Orin Dafidi 105:16-19 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Nígbà kan, ó mú kí ìyàn jà ní ilẹ̀ náà:ó ṣẹ́ ọ̀pá oúnjẹ mọ́ wọn lẹ́nu.

17. Ṣugbọn ó kọ́ rán ọkunrin kan ṣáájú wọn,Josẹfu, ẹni tí a tà lẹ́rú.

18. Wọ́n so ṣẹ́kẹ́ṣẹkẹ̀ mọ́ ọn lẹ́sẹ̀,wọ́n ti ọrùn rẹ̀ bọ irin,

19. títí ìgbà tí ohun tí ó sọ fi ṣẹ,tí OLUWA sì jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀.

Orin Dafidi 105