Orin Dafidi 104:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Yin OLUWA, ìwọ ọkàn mi,OLUWA, Ọlọrun mi, ó tóbi pupọ,ọlá ati iyì ni ó wọ̀ bí ẹ̀wù.

2. Ó fi ìmọ́lẹ̀ bora bí aṣọ,ó ta ojú ọ̀run bí ẹni taṣọ.

3. Ìwọ tí o tẹ́ àjà ibùgbé rẹ sórí omi,tí o fi ìkùukùu ṣe kẹ̀kẹ́ ogun rẹ,tí o sì ń lọ geere lórí afẹ́fẹ́.

Orin Dafidi 104