Orin Dafidi 102:22-24 BIBELI MIMỌ (BM)

22. nígbà tí àwọn orílẹ̀-èdè bá péjọ tàwọn tọba wọn,láti sin OLUWA.

23. Ó ti gba agbára mi ní àìpé ọjọ́,ó ti gé ọjọ́ ayé mi kúrú.

24. Mo ní, “Áà! Ọlọrun mi, má mú mi kúrò láyé láìpé ọjọ́,ìwọ tí ọjọ́ ayé rẹ kò lópin.”

Orin Dafidi 102