60. Ní ọjọ́ kẹsan-an ni Abidani ọmọ Gideoni, olórí àwọn ẹ̀yà Bẹnjamini mú ọrẹ tirẹ̀ wá.
61. Ọrẹ tirẹ̀ ni àwo fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadoje (130) ṣekeli, abọ́ fadaka kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ aadọrin ṣekeli. Ìwọ̀n tí wọ́n ń lò ní ibi mímọ́ ni wọ́n fi wọ̀n ọ́n. Àwo ati abọ́ náà kún fún ìyẹ̀fun kíkúnná tí a fi òróró pò, fún ẹbọ ohun jíjẹ.
62. Ara ọrẹ rẹ̀ tún ni: àwo kòtò kan, tí wọ́n fi wúrà ṣe tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ ṣekeli mẹ́wàá, tí ó sì kún fún turari.
63. Akọ mààlúù kékeré kan, àgbò kan, ọ̀dọ́ àgbò, ọlọ́dún kan, fún ẹbọ sísun,