Nọmba 33:12-16 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Wọ́n kúrò ní aṣálẹ̀ Sini, wọ́n lọ pàgọ́ sí Dofika.

13. Wọ́n kúrò ní Dofika, wọ́n lọ pàgọ́ sí Aluṣi.

14. Wọ́n kúrò ní Aluṣi, wọ́n lọ pàgọ́ sí Refidimu níbi tí wọn kò ti rí omi mu.

15. Wọ́n kúrò ní Refidimu lọ sí aṣálẹ̀ Sinai.

16. Láti aṣálẹ̀ Sinai wọ́n lọ sí Kiburotu Hataafa.

Nọmba 33