1. Ọpọlọpọ àwọn eniyan náà, atọkunrin atobinrin, bẹ̀rẹ̀ sí tako àwọn Juu, arakunrin wọn.
2. Àwọn kan ń sọ pé, “Àwa, ati àwọn ọmọ wa, lọkunrin ati lobinrin, a pọ̀, ẹ jẹ́ kí á lọ wá ọkà, kí á lè máa rí nǹkan jẹ, kí á má baà kú.”
3. Àwọn mìíràn ń sọ pé, “A ti fi ilẹ̀ oko wa yáwó, ati ọgbà àjàrà wa, ati ilé wa, kí á lè rówó ra ọkà nítorí ìyàn tí ó mú yìí.”