Nehemaya 13:14-17 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Ọlọrun mi, ranti mi, nítorí nǹkan wọnyi, kí o má sì pa gbogbo nǹkan rere tí mo ti ṣe sí tẹmpili rẹ rẹ́ ati àwọn iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.

15. Ní àkókò náà mo rí àwọn ọmọ Juda tí wọn ń fún ọtí waini ní ọjọ́ ìsinmi, tí wọ́n sì ń kó ìtí ọkà jọ, tí wọn ń dì wọ́n ru kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, tí wọn sì ń gbé waini, ati èso girepu, ati igi ọ̀pọ̀tọ́ ati oríṣìíríṣìí ẹrù wúwo wá sí Jerusalẹmu ní ọjọ́ ìsinmi, mo bá kìlọ̀ fún wọn nípa ọjọ́ tí ó yẹ kí wọ́n máa ta oúnjẹ.

16. Àwọn ọkunrin kan láti Tire pàápàá tí wọn ń gbé ààrin ìlú náà mú ẹja wá ati oríṣìíríṣìí àwọn nǹkan títà, wọ́n sì ń tà wọ́n fún àwọn eniyan Juda ati ni Jerusalẹmu ní ọjọ́ ìsinmi.

17. Mo bá àwọn ọlọ́lá Juda wí, mo ní, “Irú nǹkan burúkú wo ni ẹ̀ ń ṣe yìí, tí ẹ̀ ń rú òfin ọjọ́ ìsinmi?

Nehemaya 13