Nehemaya 1:1-3 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ìtàn Nehemaya ọmọ Hakalaya.Ní oṣù Kisilefi, ní ogún ọdún tí Atasasesi jọba ní ilẹ̀ Pasia, mo wà ní Susa tíí ṣe olú-ìlú ilẹ̀ náà,

2. Hanani, ọ̀kan ninu àwọn arakunrin mi, pẹlu àwọn kan tọ̀ mí wá láti ilẹ̀ Juda, mo bá bèèrè àwọn Juu tí wọ́n ṣẹ́kù, tí wọn kò kó lọ sóko ẹrú, mo sì tún bèèrè nípa Jerusalẹmu.

3. Wọ́n sọ fún mi pé, “Inú wahala ńlá ati ìtìjú ni àwọn tí wọ́n ṣẹ́kù, tí wọn kò kó lẹ́rú wà, ati pé odi Jerusalẹmu ti wó lulẹ̀, iná sì ti jó gbogbo ẹnu ọ̀nà rẹ̀.”

Nehemaya 1