1. Ìlú tí ń ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ gbé!Ìlú tí ó kún fún irọ́ ati ìkógun,tí àwọn adigunjalè kò fi ìgbà kan dáwọ́ dúró níbẹ̀!
2. Pàṣán ń ró, ẹṣin ń yan,kẹ̀kẹ́ ogun ń pariwo!
3. Àwọn ẹlẹ́ṣin ti múra ìjàpẹlu idà ati ọ̀kọ̀ tí ń kọ mànà.Ọpọlọpọ ni wọ́n ti pa sílẹ̀,òkítì òkú kúnlẹ̀ lọ kítikìti;òkú sùn lọ bẹẹrẹ láìníye,àwọn eniyan sì ń kọlu àwọn òkúbí wọn tí ń lọ!