Matiu 11:14-17 BIBELI MIMỌ (BM)

14. Bí ẹ bá fẹ́ gbà á, Johanu ni Elija, tí ó níláti kọ́ wá.

15. Ẹni tí ó bá ní etí láti fi gbọ́ràn, kí ó gbọ́.

16. “Kí ni ǹ bá fi ìran yìí wé? Ó dàbí àwọn ọmọde tí wọ́n jókòó ní ọjà, tí wọn ń ké sí àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn pé.

17. ‘A lù fun yín, ẹ kò jó, a pe òkú, ẹ kò ṣọ̀fọ̀.’

Matiu 11