Maku 6:9-15 BIBELI MIMỌ (BM)

9. Kí wọn wọ bàtà, ṣugbọn kí wọn má wọ ẹ̀wù meji.

10. Ó tún fi kún un fún wọn pé, “Ilékílé tí ẹ bá wọ̀, níbẹ̀ ni kí ẹ máa gbé títí ẹ óo fi kúrò ní ìlú náà.

11. Ibikíbi tí wọn kò bá ti gbà yín, tí wọn kò gbọ́ ọ̀rọ̀ yín, ẹ jáde kúrò níbẹ̀, kí ẹ gbọn eruku ẹsẹ̀ yín sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀rí láti kìlọ̀ fún wọn.”

12. Bí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mejila ti ń lọ, wọ́n ń waasu pé kí gbogbo eniyan ronupiwada.

13. Wọ́n ń lé ọpọlọpọ ẹ̀mí èṣù jáde, wọ́n ń fi òróró pa ọpọlọpọ aláìsàn lára, wọ́n sì ń mú wọn lára dá.

14. Hẹrọdu ọba gbọ́ nípa Jesu, nítorí òkìkí rẹ̀ kàn. Àwọn kan ń sọ pé, “Johanu Onítẹ̀bọmi ni ó jí dìde ninu òkú, òun ni ó jẹ́ kí ó lè máa ṣe iṣẹ́ ìyanu bẹ́ẹ̀.”

15. Ṣugbọn àwọn mìíràn ń wí pé, “Elija ni.”Àwọnmìíràn ní, “Wolii ni, bí ọ̀kan ninu àwọn wolii àtijọ́.”

Maku 6